Isaiah 17:1-3

Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ ní ti Damasku

1 aỌ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Damasku:

“Kíyèsi i, Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́
ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.
2Àwọn ìlú Aroeri ni a ó kọ̀sílẹ̀
fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn síbẹ̀,
láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.
3Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu,
àti agbára ọba kúrò ní Damasku;
àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá
gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Copyright information for YorBMYO